Aigbagbo bila! temi l’Oluwa
On o si dide fun igbala mi;
Ki nsa ma gbadura, On o se ranwo:
’Gba Krist wa lodo mi, ifoiya ko si.
B’ona mi mi ba su, on l’o sa nto mi,
Ki nsa gboran sa, On o si pese;
Bi iranlowo eba gbogba saki,
Oro t’enu Re so y’o bori dandan.
Ife t’o nfi han, ko je ki nro pe
Y’o fi mi sile ninu wahala;
Iranwo ti mo si nri lojojumo,
O nki mi laiya pe, emi o la ja.
Emi o se kun tori iponju,
Tabi irora? O ti so tele!
Mo m’ oro Re p’ awon ajogun ’gbala,
Nwon ko le s’aikoja larin wahala.
Eda ko le so kikiro ago
T’Olugbala mu, k’elese le ye;
Aiye Re tile buru ju temi lo,
Jesu ha le jiya, K’emi si ma sa!
Nje b’ohun gbogbo ti nsise ire
Adun n’ikoro, onje li ogun
B’ona tile koro, sa ko ni pe mo,
Gbana ori ’segun yio ti dun to!