E maa te siwaju, Kriatian ologun
Maa tejumo mo Jesu t’o mbe niwaju;
Kristi Oluwa wa niBalogun wa
Wo! asia re wa niwaju ogun.
Egbe
E ma te siwaju Kristain ologun
Sa tejumo Jesu t’o mbe niwaju.
Ni oruko Jesu ogun esu sa,
Nje Kristian ologun, ma nso si segun;
Orun apadi mi ni hiho iyin
Ara gbohun yin ga, gb’orin yin soke.
Egbe
Bi egbe ogun nla, n’Ijo Olorun,
Ara, a nrin l’ona t’awon mimo
A ko ya wa n’ipa, egebe kan ni wa
Okan L’eko n’ife ati n’ireti.
Egbe
Ite at’ijoba wonyi le parun,
Sugbon Ijo jesu y’o wa titi lai,
Orun apadi ko le bor’ ijo yi
A n’ileri Kristi, eyi ko le ye.
Egbe
E ma ba ni kalo, eyin eyan;
D’ohun yin po mo, lorin isegun,
Ogo, iyin, ola fun Kristi Oba
Eyi ni y’o ma je orin wa titi.
Egbe