Awon oku ninu Kristi ni yio si ko jinde: Nigbanaa li a si gba awa ti o wa laaye ti o si ku lehin soke pelu won ninu awosanma, lati pade Oluwa li oju orun.@1 Tessalonika 4:16-17
aworan
Sabine Baring-Gould
1834–1924
National Portrait Gallery

button

Sabine Baring-Gould, 1864 (On the Resurrection Morning); a ko mo eniti to seitumo.

Christopher E. Willing (1830–1904) (🔊 pdf nwc).

L’owuro ojo ajinde,
T’ara t’okan y’o pade,
Ekun, ’kanu on irora
Y’o dopin.

Nihin won ko le sai pinya
Ki ara ba le sinmi,
K’o si fi idakeroro
Sun fonfon.

Fun ’gba die ara are yi
L’a gbe s’ibi ’simi re;
Titi di imole oro
Ajinde.

Okan to kanu nisisiyi
To si ngbadura kikan,
Y’o bu s’orin ayo l’ojo
Ajinde.

Ara at’okan y’o dapo
Ipinya ko ni si mo
Nwon o ji l’aworan Kristi
Ni’Telorun.

A! ewa na at’ayo na
Y’o ti po to l’Ajinde!
Y’o duro, b’orun at’aiye
Ba fo lo.

L’oro ojo ajinde wa
’Boji y’o m’ oku re wa;
Baba, iya, omo, ara
Yo pade.

Si’dapo ti ofun bayi
Jesu masai ka wa ye
N’nu ku, dajo ka le ro
M’Agbelebu.