🡅 🡇 🞮

NIPA IFE OLUGBALA

Nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùgbàlà rẹ. Àìsáyà 43:3

Ma­ry B. Pe­ters, Hymns In­tend­ed to Help the Com­mun­ion of Saints (Lon­don: Nis­bet, 1847) (Through the Love of God Our Sav­ior). Onitumo aimọ.

Ev­en­song Tho­mas B. South­gate (1814–1868) (🔊 ). Ohun orin ipe yiyan:

Nipa ife Olugbala
Ki y’o si nkan;
Ojurere Re ki pada
Ki y’o si nkan.
Owon l’eje t’o wo wa san
Pipe l’edidi or’-ofe
Agbara l’owo t’o gba ni,
Ko le si nkan.

Bi a wa ninu iponju
Ki y’o si nkan:
Igbala kikun ni ti wa,
Ki y’o si nkan;
Igbekele Olorun dun,
Gbigbe ininu Kristi l’ere,
Emi si nso wa di mimo,
Ko le si nkan

Ojo ola yio dara
Ki y’o si nkan.
’Gbagbo le korin n’ iponji,
Ki y’o si nkan.
A gbekele ’fe Baba wa;
Jesu nfun wa l’ohun gbogbo
Ni yiye tabi ni kiku
Ko le si nkan.