Iranse Oluwa!
E duro nid’ ise;
E toju oro Re mimo,
E ma sona Re sa.
Je k’ imole nyin tan,
E tun fitila se;
E damure girigiri,
Oruko Re l’ eru.
Sora! l’ ase Jesu,
B’a ti nse ko jina
B’o ba kuku ti kan ’lekun
Ki e si fun logan.
Iranse ’re l ’eni
Ti a ba nipo yi;
Ayo l ’ on o fi r’ Oluwa
Y’o f’ ola de l’ ade.
Kristi tikalare
Y’o te tabili fun
Y’o gb’ ori iranse na ga
Larin egbe Angel.