Kristian, ma ti ’wa ’simi,
Gbo b’Angeli re ti nwi;
Ni aarin ota l’o wa;
Maa sora.
Ogun orun-apadi,
T’a ko ri, nko ‘ra won jo;
Nwon nso ijafara re;
Maa sora.
Wo hamora-orun re,
Wo losan ati loru;
Esu ba, o ndode re;
Maa sora.
Awon t’o segun saju,
Nwon nwo wa b’awa ti nja:
Nwon nfi ohun kan wipe,
Maa sora.
Gbo b’Oluwa re ti wi,
Eniti iwo feran;
F’oro Re si okan re;
Maa sora.
Maa sora bi enipe,
Nibe ni’segun re wa;
Gbadura fun ‘ranlowo;
Maa sora.